Eksodu 23:24
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
24 Ìwọ kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún òrìṣà wọn, bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n, tàbí kí ẹ tẹ̀lé ìṣe wọn. Kí ìwọ kí ó si wó wọn lulẹ̀, kí ìwọ kí ó sì fọ́ ère òkúta wọ́n túútúú.
Read full chapter
Eksodu 34:6
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
6 (A)Ó sì kọjá níwájú Mose, ó sì ń ké pé, “Olúwa, Olúwa, Ọlọ́run aláàánú àti olóore-ọ̀fẹ́, ẹni tí ó lọ́ra láti bínú, tí ó pọ̀ ní ìfẹ́ àti olóòtítọ́,
Read full chapter
Eksodu 34:7
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
7 Ẹni tí ó ń pa ìfẹ́ mọ́ fún ẹgbẹ̀rún (1,000), ó sì ń dáríjì àwọn ẹni búburú, àwọn ti ń ṣọ̀tẹ̀ àti ẹlẹ́ṣẹ̀. Síbẹ̀ kì í fi àwọn ẹlẹ́bi sílẹ̀ láìjìyà; Ó ń fi ìyà jẹ ọmọ àti àwọn ọmọ wọn fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba dé ìran kẹta àti ẹ̀kẹrin.”
Read full chapter
Eksodu 34:14
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
14 (A)Ẹ má ṣe sin ọlọ́run mìíràn, nítorí Olúwa, orúkọ ẹni ti ń jẹ́ Òjòwú, Ọlọ́run owú ni.
Read full chapter
Deuteronomi 4:24
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
24 Torí pé iná ajónirun ni Olúwa Ọlọ́run yín, Ọlọ́run owú ni.
Read full chapter
Deuteronomi 5:9
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
9 Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ orí ara rẹ ba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n; nítorí Èmi Olúwa Ọlọ́run rẹ, Ọlọ́run owú ni mí, tí ń bẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wò lára àwọn ọmọ, láti ìran kẹta títí dé ẹ̀kẹrin nínú àwọn tí ó kórìíra mi.
Deuteronomi 5:10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
10 Èmi a sì máa fi àánú hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ó fẹ́ mi, tí wọ́n sì ń pa òfin mi mọ́.
Deuteronomi 7:9
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
9 Nítorí náà ẹ mọ̀ dájúdájú pé Olúwa Ọlọ́run yín, Òun ni Ọlọ́run, Ọlọ́run olóòtítọ́ ni, tí ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìran, àwọn tí ó fẹ́ ẹ tí ó sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.