Luku 21:21-24
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
21 Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Judea sálọ sórí òkè; àti àwọn tí ń bẹ láàrín rẹ̀ kí wọn jáde kúrò; kí àwọn tí ó sì ń bọ̀ ní ìgbèríko má ṣe wọ inú rẹ̀ wá. 22 Nítorí ọjọ́ ẹ̀san ni ọjọ́ wọ̀nyí, kì a lè mú ohun gbogbo tí a ti kọ̀wé rẹ̀ ṣẹ. 23 (A)Ṣùgbọ́n ègbé ni fún àwọn tí ó lóyún, àti àwọn tí ó fi ọyàn fún ọmọ mu ní ọjọ́ wọ̀nyí! Nítorí tí ìpọ́njú púpọ̀ yóò wà lórí ilẹ̀ àti ìbínú sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. 24 (B)Wọn ó sì ti ojú idà ṣubú, a ó sì dìwọ́n ní ìgbèkùn lọ sí orílẹ̀-èdè gbogbo; Jerusalẹmu yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aláìkọlà, títí àkókò àwọn aláìkọlà yóò fi kún.
Read full chapter
Luku 21:6
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
6 (A)“Ohun tí ẹ̀yin ń wò wọ̀nyí, ọjọ́ ń bọ̀, nígbà tí a kì yóò fi òkúta kan sílẹ̀ lórí èkejì tí a kì yóò wó lulẹ̀.”
Read full chapter
Isaiah 29:3
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
3 Èmi yóò sì wà ní bùba yí ọ ká níbi gbogbo;
Èmi yóò sì fi ilé ìṣọ́ yí ọ ká:
èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìdó ti ni mi dojúkọ ọ́.
Jeremiah 6:6
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
6 Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí:
“Ẹ ké àwọn igi náà lulẹ̀
kí ẹ sì mọ odi ààbò yí Jerusalẹmu ká.
Èyí ni ìlú títóbi tí a ó bẹ̀wò,
nítorí pé ó kún fún ìninilára.
Esekiẹli 4:2
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
2 Kí o sì dó tì í, kí o sì mọ ilé ìṣọ́ tì í, kí o sì mọ odi tì í, kí o sì gbé ogun sí i, kí o sì to òòlù yí i ká.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.