Matiu 24:17-18
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
17 Kí ẹni tí ó wà lórí ilé rẹ̀ má ṣe sọ̀kalẹ̀ wá mú ohunkóhun jáde nínú ilé rẹ̀. 18 Kí àwọn tí ó sì wà lóko má ṣe darí wá sí ilé láti mú àwọn aṣọ wọn.
Read full chapter
Marku 13:15-16
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
15 Kí ẹni ti ń bẹ lórí ilé má ṣe sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ilé, bẹ́ẹ̀ ni kí ó má sì ṣe wọ inú rẹ̀, láti mú ohunkóhun jáde nínú ilé rẹ̀. 16 Kí ẹni tí ó wà lóko má ṣe padà sẹ́yìn láti wá mú aṣọ rẹ̀.
Read full chapter
Luku 21:21
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
21 Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Judea sálọ sórí òkè; àti àwọn tí ń bẹ láàrín rẹ̀ kí wọn jáde kúrò; kí àwọn tí ó sì ń bọ̀ ní ìgbèríko má ṣe wọ inú rẹ̀ wá.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.