Eksodu 25:8
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
8 “Nígbà náà ni ìwọ yóò jẹ́ kí wọn kọ́ ibi mímọ́ fún mi. Èmi yóò sì máa gbé ní àárín wọn.
Read full chapter
Eksodu 29:45
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
45 Nígbà náà ni èmi yóò máa gbé láàrín àwọn ọmọ Israẹli, èmi yóò sì máa ṣe Ọlọ́run wọn.
Read full chapter
Lefitiku 26:12
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
12 Èmi yóò wà pẹ̀lú yín: Èmi yóò máa jẹ́ Ọlọ́run yín: Ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ènìyàn mi.
Read full chapter
Jeremiah 31:1
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
31 “Nígbà náà, Èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo ìdílé ìran Israẹli, àwọn náà yóò sì jẹ́ ènìyàn mi,” ni Olúwa wí.
Read full chapter
2 Kọrinti 6:16
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
16 (A)Ìrẹ́pọ̀ kín ni tẹmpili Ọlọ́run ní pẹ̀lú òrìṣà? Nítorí ẹ̀yin ní tẹmpili Ọlọ́run alààyè; gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti wí pé:
“Èmi á gbé inú wọn,
èmi o sì máa rìn láàrín wọn,
èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn,
wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi.”
Ìfihàn 21:3
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
3 (A)Mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti orí ìtẹ́ náà wá, ń wí pé, “Kíyèsi i, àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn, òun ó sì máa bá wọn gbé, wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀, àti Ọlọ́run tìkára rẹ̀ yóò wà pẹ̀lú wọn, yóò sì máa jẹ́ Ọlọ́run wọn.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.