Add parallel Print Page Options

16 (A)Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ẹnìkejì rẹ.

Read full chapter

(A)Má ṣe lọ́wọ́ nínú ẹ̀sùn èké, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ pa aláìṣẹ̀ tàbí olódodo ènìyàn, nítorí Èmi kò ní dá ẹlẹ́bi láre.

Read full chapter

20 Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ẹnìkejì rẹ.

Read full chapter

Ẹlẹ́rìí

15 (A)Ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo kò tó láti dájọ́ ọkùnrin kan tí o fi ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ yóò wù kí ó lè ṣẹ̀ lẹ́bi. A ó fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ láti orí ẹ̀rí ẹni méjì tàbí mẹ́ta.

16 (B)Tí alárankàn ẹlẹ́rìí èké bá dúró láti fi ẹ̀sùn ẹ̀ṣẹ̀ kan ọkùnrin kan, 17 àwọn méjèèjì tí àríyànjiyàn wà láàrín wọn gbọdọ̀ dúró níwájú Olúwa níwájú àwọn àlùfáà àti àwọn adájọ́ tí ó wà ní ibi iṣẹ́ ní ìgbà náà. 18 Àwọn adájọ́ gbọdọ̀ ṣe ìwádìí fínní fínní bí ẹ̀rí bá sì jẹ́ irọ́, tí ó fi ẹ̀rí èké sun arákùnrin rẹ̀, 19 (C)nígbà náà ni kí ó ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ṣe fẹ́ ṣe sí arákùnrin rẹ̀. O ní láti wẹ búburú kúrò láàrín rẹ. 20 Àwọn ènìyàn tókù yóò gbọ́ nípa èyí, wọn yóò sì bẹ̀rù, kí irú nǹkan búburú bẹ́ẹ̀ máa tún sẹ̀ mọ́ láàrín yín. 21 (D)Má ṣe fi àánú hàn, ẹ̀mí fún ẹ̀mí, ojú fún ojú, eyín fún eyín, apá fún apá, ẹsẹ̀ fún ẹsẹ̀.

Read full chapter