Isaiah 13:8
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
8 Ẹ̀rù yóò gbá wọn mú,
ìrora àti ìpayínkeke yóò dìwọ́n mú,
wọn yóò kérora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí.
Ẹnìkínní yóò wo ẹnìkejì rẹ̀ pẹ̀lú ìpayà
ojú wọn á sì gbinájẹ.
Hosea 13:13
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
13 Ìrora bí obìnrin tó fẹ́ bímọ ti dé bá a
Ṣùgbọ́n ó jẹ́ ọmọ tí kò lọ́gbọ́n
Nígbà tí àsìkò tó,
ó kọ̀ láti jáde síta láti inú.
Matiu 4:9
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
9 Ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ, bí ìwọ bá foríbalẹ̀ tí o sì sìn mi.”
Read full chapter
1 Tẹsalonika 5:3
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
3 (A)Ní àkókò gan an tí àwọn ènìyàn yóò máa wí pé, “Àlàáfíà àti ààbò,” nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ìrọbí obìnrin tí ó lóyún, wọn kò sí ni rí ibi ààbò láti sá sí.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.