Johanu 20:14-18
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
14 (A)Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó yípadà, ó sì rí Jesu dúró, kò sì mọ̀ pé Jesu ni.
15 Jesu wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún? Ta ni ìwọ ń wá?”
Òun ṣe bí olùṣọ́gbà ní í ṣe, ó wí fún un pé, “Alàgbà, bí ìwọ bá ti gbé e kúrò níhìn-ín yìí, sọ ibi tí ìwọ tẹ́ ẹ sí fún mi, èmi yóò sì gbé e kúrò.”
16 Jesu wí fún un pé, “Maria!”
Ó sì yípadà, ó wí fún un ní èdè Heberu pé, “Rabboni!” (èyí tí ó túmọ̀ sí “Olùkọ́”).
17 (B)Jesu wí fún un pé, “Má ṣe fi ọwọ́ kàn mí; nítorí tí èmi kò tí ì gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Baba mi: ṣùgbọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin mi, sì wí fún wọn pé, ‘Èmi ń gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Baba mi, àti Baba yín: àti sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi, àti Ọlọ́run yín.’ ”
18 (C)Maria Magdalene wá, ó sì sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, “Òun ti rí Olúwa!” Àti pé, ó sì ti fi nǹkan wọ̀nyí fún òun.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.