Add parallel Print Page Options

29 (A)“Lójúkan náà, lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,

“ ‘ni oòrùn yóò ṣókùnkùn,
    òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ hàn;
àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò já sílẹ̀,
    agbára ojú ọ̀run ni a ó mì tìtì.’

30 (B)“Nígbà náà ni ààmì Ọmọ Ènìyàn yóò sì fi ara hàn ní ọ̀run, nígbà náà ni gbogbo ẹ̀yà ayé yóò káàánú, wọn yóò sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò máa ti ojú ọ̀run bọ̀ ti òun ti ògo àti agbára ńlá.

Read full chapter

24 “Ṣùgbọ́n ni ọjọ́ wọ̀nyí lẹ́yìn ìpọ́njú tí mo sọ yìí,

“ ‘oòrùn yóò ṣókùnkùn,
    òṣùpá kò ní tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.
25 Àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú yóò já lulẹ̀ láti ojú ọ̀run,
    àti agbára tí ń bẹ ní ọ̀run ni a ó sì mì tìtì.’

26 (A)“Nígbà náà ni gbogbo ayé yóò sì rí i tí Èmi Ọmọ Ènìyàn yóò máa bọ̀ wá láti inú àwọsánmọ̀ pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.

Read full chapter