Romu 11:25
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Gbogbo Israẹli tòótọ́ ni yóò ní ìgbàlà
25 (A)Ará, èmi kò ṣá fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó wà ní òpè ní ti ohun ìjìnlẹ̀ yìí, kí ẹ̀yin má ba á ṣe ọlọ́gbọ́n ní ojú ara yín, pé ìfọ́jú bá Israẹli ní apá kan, títí kíkún àwọn Kèfèrí yóò fi dé.
Read full chapter
Romu 15:5
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
5 (A)Kí Ọlọ́run, ẹni tí ń fún ni ní sùúrù àti ìtùnú fún yin láti ní inú kan sí ara yín gẹ́gẹ́ bí i Jesu Kristi,
Read full chapter
1 Kọrinti 1:10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìyapa nínú ìjọ Ọlọ́run
10 Mo bẹ̀ yín ẹ̀yin ara, ní orúkọ Olúwa wa Jesu Kristi, pé kí gbogbo yín fohùn ṣọ̀kan kí ó máa ṣe sí ìyapa láàrín yín, àti pé kí a lè ṣe yín pé ní inú àti ìmọ̀ kan náà.
Read full chapter
2 Kọrinti 13:11
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìkíni ìkẹyìn
11 Ní àkótán, ará ó dì gbòóṣe, ẹ ṣe àtúnṣe ọ̀nà yín, ẹ tújúká, ẹ jẹ́ onínú kan, ẹ máa wà ní àlàáfíà, Ọlọ́run ìfẹ́ àti ti àlàáfíà yóò wà pẹ̀lú yín.
Read full chapter
Filipi 2:2
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
2 síbẹ̀ ẹ mú ayọ̀ mi kún nínú ìṣọ̀kan yín, nípa ìfẹ́ kan náà, wíwà ní ẹ̀mí kan náà àti ète kan náà.
Read full chapter
Filipi 4:2
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú
2 Èmi ń bẹ̀ Euodia, mo sì ń bẹ Sintike, kí wọn ní inú kan náà nínú Olúwa.
Read full chapter
Òwe 3:7
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
7 (A)Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara à rẹ
bẹ̀rù Olúwa kí o sì kórìíra ibi.
Òwe 26:12
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
12 Ǹjẹ́ o rí ènìyàn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara rẹ̀?
Ìrètí ń bẹ fún aláìgbọ́n ènìyàn jù ú lọ.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.