Romu 3:5
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
5 (A)Ṣùgbọ́n bí àìṣòdodo wa bá fi òdodo Ọlọ́run hàn, kín ni àwa ó wí? Ọlọ́run ha jẹ́ àìṣòdodo bí? Nígbà tí ó bá ń fi ìbínú rẹ̀ hàn (Mo fi ṣe àkàwé bí ènìyàn).
Read full chapter
Romu 3:24-25
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
24 (A)Àwọn ẹni tí a ń dá láre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, nípa ìdáǹdè tí ó wà nínú Kristi Jesu: 25 Ẹni tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ láti jẹ́ ètùtù nípa ìgbàgbọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, láti fi òdodo rẹ̀ hàn nítorí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti kọjá, nínú ìpamọ́ra Ọlọ́run:
Read full chapter
Efesu 1:7
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
7 (A)Nínú rẹ̀ ni àwa rí ìràpadà gba nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ àti ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ní ìbámu pẹ̀lú ọrọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run
Read full chapter
1 Tẹsalonika 1:10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
10 (A)àti láti fi ojú ṣọ́nà fún ìpadàbọ̀ Ọmọ rẹ̀ láti ọ̀run wá, ẹni tí ó jí dìde kúrò nínú òkú, Jesu, ẹni tí ó gbà wá lọ́wọ́ ìbínú tí ń bọ̀.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.