Romu 5:8
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
8 (A)Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìfẹ́ òun pàápàá sí wa hàn nínú èyí pé, nígbà tí àwa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.
Read full chapter
Romu 8:32
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
32 (A)Níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ti fi Ọmọ rẹ̀ fún wa, ǹjẹ́ ó ha tún le ṣòro fún un láti fún wa ní ohunkóhun bí?
Read full chapter
Efesu 2:4
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
4 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run, ẹni tí í ṣe ọlọ́rọ̀ ni àánú, nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí ó fi fẹ́ wa,
Read full chapter
1 Johanu 4:9-10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
9 (A)Nípa èyí ni a gbé fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn nínú wa, nítorí tí Ọlọ́run rán ọmọ bíbí rẹ̀ nìkan ṣoṣo sì ayé, kí àwa lè yè nípasẹ̀ rẹ̀. 10 (B)Nínú èyí ni ìfẹ́ wà, kì í ṣe pé àwa fẹ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n òun fẹ́ wá, ó sì rán Ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wa.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.