Saamu 64
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
64 Gbóhùn mi, Ọlọ́run, bí mo ti ń sọ àròyé mi
pa ọkàn mi mọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀rù àwọn ọ̀tá.
2 Pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ àwọn ènìyàn búburú
kúrò nínú ọ̀pọ̀ igbe lọ́wọ́ ìrúkèrúdò oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
3 Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bí idà,
wọ́n sì fa ọrun wọn le láti tafà wọn, àní ọ̀rọ̀ kíkorò.
4 Wọ́n tafà ní ìkọ̀kọ̀ sí àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀:
wọ́n tafà si lójijì, wọn kò sì bẹ̀rù.
5 Wọ́n, gba ara wọn níyànjú nínú èrò búburú,
wọ́n sọ̀rọ̀ lórí dídẹkùn sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀
wọ́n wí pé, “Ta ni yóò rí wa?”
6 Wọ́n gbìmọ̀ àìṣòdodo, wọ́n wí pé,
“A wa ti parí èrò tí a gbà tán”
lóòótọ́ àyà àti ọkàn ènìyàn kún fún àrékérekè.
7 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ta wọ́n ní ọfà;
wọn ó sì gbọgbẹ́ lójijì.
8 Ahọ́n wọn yóò sì dojú ìjà kọ wọ́n, yóò sì run wọ́n,
Gbogbo ẹni tí ó bá rí wọn yóò sì mi orí fún wọn.
9 Gbogbo ènìyàn yóò máa bẹ̀rù
wọn ó kéde iṣẹ́ Ọlọ́run
wọn ó dúró lé ohun tí ó ṣe.
10 Jẹ́ kí olódodo kí ó yọ̀ nínú Olúwa
yóò sì rí ààbò nínú rẹ̀.
Gbogbo ẹni ìdúró ṣinṣin ní ọkàn yóò máa yìn ín.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.